Ọjà Pàṣípàrọ̀ jẹ́ ètò ṣíṣe pàṣípàrọ̀ ohun-ìní tàbí iṣẹ́ láàárín ènìyàn méjì láyé àtijó nígbà tí wọn kò ì tíì ṣẹ̀dá owó fún káràkátà ṣíṣe. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tí ó bá ní ìṣù ṣùgbọ́n tí ó nílò gaàrí yóò wá ẹlòmíràn tí ó ní gaàrí tí ó sìn nílò iṣu láti ṣe pàṣípàrọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ọjà Pàṣípàrọ̀ jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe káràkátà láyé àtijó láìlo owó.