Ascariasis

Ascariasis
AscariasisAscaris lumbricoides
AscariasisAscaris lumbricoides
Ascaris lumbricoides
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B77. B77.
ICD/CIM-9127.0 127.0
OMIM604291
DiseasesDB934
MedlinePlus000628

Ascariasis jẹ́ àrùn tí kòkòrò ajọ̀fẹ́ tí a npé ní aràn alára rógódó Ascaris lumbricoides nṣe òkùnfà rẹ̀. Àkóràn àrùn náà kò ní ààmì àìsàn kankan lára marundinlaadọrun nínú ọgọrun (85%) àwọn ènìyàn tó ti ní àrùn náà, pàápàá bí iye àwọn aràn náà bá kèrè. Àwọn ààmì àìsàn a má a pọ̀ síi pẹ̀lú iye aràn tó wà lára, lára irú àwọn ààmì bẹ́ẹ̀ sì ni àìlèmíkanlẹ̀ àti ibà ní ìbẹ̀rẹ̀ àìsàn náà. Àwọn ààmì àìsàn bíi inú wíwú, inú rírun àti ìgbẹ́ gbuuru lè tẹ̀lé èyí. Àwọn ọmọdé ni ó má a nsábà ní àkóràn àrùn náà, láàárín àwọn ọmọdé bẹ́ẹ̀, àkóràn àrùn náà tún lè ṣe òkùnfa àìlẹ́ranlára, àìtó èròjà oúnjẹ lára àti àwọn ìṣòro nípa ẹ̀kọ́-kíkọ́.

Àkóràn àrùn náà a má a wáyé nípasẹ̀ jíjẹ oúnjẹ tàbí mímu omi tí ẹyin aràn tí à npè ní Ascaris náà, èyítí ó ti inú ìgbọ̀nsẹ̀ jáde wá, bá ti kó sí, tí ó sì ti sọ di àìmọ́. À ó pa àwọn ẹyin náà nínú ìfun, àwọn aràn náà a sì gbẹ́ ihò sínú ògiri ikùn ènìyàn, wọn a sì gba ibẹ̀ lọ sínú àwọn ẹ̀dọ̀fóró nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀. Níbẹ̀ wọn yóò wọ inú àwọn àpò atẹ́gùn inú ẹ̀dọ̀fóró, wọn yóò sì ṣàn lọ sókè nínú ọ̀nà-ọ̀fun, níbití a ó ti wú wọn jáde bí ikọ́, tí a ó sì gbé wọn mì. Àwọn ìdin náà yóò sì gba inú ikùn kọjá fún ìgbà kejì sínú ìfun níbití wọn yóò ti dàgbà sí aràn nlá.

Ìdènà àrùn náà níí ṣe pẹ̀lú ìmọ́tótó, èyítí ó kan mímú ìlọsíwájú bá níní ànfàní sí ilé-ìyàgbẹ́ àti dída ìgbẹ́ nù ní ọ̀nà tí ó tọ́. Ọwọ́-fífọ̀ pẹ̀lú ọṣẹ farahàn bí ààbò tó péye. Ní àwọn agbègbè ibití iye ènìyàn tó ju méjìlélógún nínú ọgọrun (20%) lọ ti ní àkóràn àrùn náà, a dámọ̀ràn pé kí a ṣe ìtọ́jú gbogbo ènìyàn láti ìgbà dé ìgbà ní tẹ̀lé-n-tẹ̀lé. Wíwáyé àrùn náà lára ẹnití ó ti níi rí jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀. Kò sí àjẹsára. Àwọn ìtọ́jú tí Àjọ Ìlera fún Àgbáyé dámọ̀ràn ni àwọn egbògi bíi albendazole, mebendazole, levamisole tàbí pyrantel pamoate. Àwọn egbògi mìíràn tó tún má a nṣiṣẹ́ ni tribendimidine àti nitazoxanide.

<!—Àtànká àti Ìṣàkóso àtànká àrùn --> Iye àwọn ènìyàn tó tó bílíọ̀nù 0.8 sí 1.2 káàkiri àgbáyé ni ó ní àrùn ascariasis, tí àwọn àwùjọ tó sì ní àrùn náà púpọ̀ jùlọ sì jẹ́ àwọn ará Gúsù Sahara Afirika, Amẹrika Latini, àti Eṣia. Èyí mú kí àrùn ascariasis jẹ́ ẹ̀yà àkóràn aràn ajọ̀fẹ́ nípasẹ̀ iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀ tó wọ́pọ̀ júlọ. Ní ọdún 2010, ó ṣe òkùnfà ikú àwọn ènìyàn tó tó 2,700, èyítí ó wálẹ̀ láti ènìyàn 3,400 tó kú ní ọdún 1990. Oríṣi aràn Ascaris mìíràn a má a ran àwọn ẹlẹ́dẹ̀.

References

  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 Dold, C; Holland, CV (Jul 2011). "Ascaris and ascariasis.". Microbes and infection / Institut Pasteur 13 (7): 632–7. doi:10.1016/j.micinf.2010.09.012. PMID 20934531. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 2.7 2.8 Hagel, I; Giusti, T (Oct 2010). "Ascaris lumbricoides: an overview of therapeutic targets.". Infectious disorders drug targets 10 (5): 349–67. doi:10.2174/187152610793180876. PMID 20701574. 
  3. "Soil-transmitted helminth infections Fact sheet N°366". World Health Organization. June 2013. 
  4. Ziegelbauer, K; Speich, B; Mäusezahl, D; Bos, R; Keiser, J; Utzinger, J (Jan 2012). "Effect of sanitation on soil-transmitted helminth infection: systematic review and meta-analysis.". PLoS medicine 9 (1): e1001162. doi:10.1371/journal.pmed.1001162. PMC 3265535. PMID 22291577. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3265535. 
  5. Fung, IC; Cairncross, S (Mar 2009). "Ascariasis and handwashing.". Transactions of the Royal Society of Tropical Medicine and Hygiene 103 (3): 215–22. doi:10.1016/j.trstmh.2008.08.003. PMID 18789465. 
  6. Jia, TW; Melville, S; Utzinger, J; King, CH; Zhou, XN (2012). "Soil-transmitted helminth reinfection after drug treatment: a systematic review and meta-analysis.". PLoS neglected tropical diseases 6 (5): e1621. doi:10.1371/journal.pntd.0001621. PMC 3348161. PMID 22590656. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3348161. 
  7. 7.0 7.1 Keiser, J; Utzinger, J (2010). "The drugs we have and the drugs we need against major helminth infections.". Advances in parasitology 73: 197–230. doi:10.1016/s0065-308x(10)73008-6. PMID 20627144. 
  8. Fenwick, A (Mar 2012). "The global burden of neglected tropical diseases.". Public health 126 (3): 233–6. doi:10.1016/j.puhe.2011.11.015. PMID 22325616. 
  9. Lozano, R (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010.". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604.